SỌ FÚN WỌN PÉ MO FẸ́RÀN WON

SỌ FÚN WỌN PÉ MO FẸ́RÀN WON

NITORI Ọlọ́run fẹ́ araye to bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, ti o fi ọmọ bibi Rẹ̀ nikansoso fun wa, ki ẹnikẹ́ni to ba gbagbọ, maṣe ṣègbé, sùgbón ki o le ni iye ainipekun.” – JOHANU 3:16

Ọlọ́run nílò ìdílé O si ńfẹ́ láti jẹ́ Bàbá fuń wa. A ṣe ẹ̀dá wa lati ni ìbánidọ́rẹ̀é pẹ̀lú Rẹ̀ àti wípé a jẹ́ ọmọkùnrin ati ọmọbìrin Rẹ̀, kí abàálè gbé ìgbé ayé ànító ati àníṣẹ́kù ti Kristi ku fun, lati fifun wa. Eyi túmọ̀ si wipe, ofẹ́ ki a fẹ̀yìnti Oun, ki a gbẹkẹle Oun, ki a fẹran Rẹ, ki asi fi aaye gba lati fẹran wa pada.

O fẹ́ ki a gbẹ́kẹ̀lé oun, ati wipe ki a kepe Oun nigbati aba nilo Ohun kan: O fẹ ni Ibanidọre pẹlu enìkọ̀ọ̀kan wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni a nfi ojú gbòòrò wo Johanu3:16. Bẹ́ẹ̀ ni, momọ̀ pe Jesu ku fun gbogbo araye, sugbon eyi kii ṣe gbogbo gboo eniyan nikan bi kose pe o ku fun enìkọ̀ọ̀kan wa, ati fun ìwọ pẹ̀lú.

O jẹ́ òtítọ́ pe ti o ba jẹ́ ìwọ nikan ni o wa lórílẹ̀ ayé, Jesu ko ba ku fun ìwọ nikan, ko ba fi ara da iya fun ìwọ nikan. Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ púpọ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ ko si lopin. Jer31:3

Facebook icon Twitter icon Instagram icon Pinterest icon Google+ icon YouTube icon LinkedIn icon Contact icon